Daniel 5:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni a mu Danieli wá siwaju ọba. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Iwọ ni Danieli nì, ti iṣe ti inu awọn ọmọ igbekun Juda! awọn ẹniti ọba, baba mi kó lati ilẹ Juda wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nigbà náà ni a mú Dáníẹ́lì wá ṣíwájú ọba, ọba sì sọ fún-un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára àwọn tí bàbá mi mú ní ìgbékùn láti Júdà!