Daniel 5:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Beṣasari bá pàṣẹ, pé kí wọ́n gbé ẹ̀wù elése àlùkò, ti àwọn olóyè, wọ Daniẹli, kí wọ́n sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Wọ́n kéde ká gbogbo ìjọba pé Daniẹli ni igbá kẹta ní ìjọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Belṣassari paṣẹ, nwọn si wọ̀ Danieli li aṣọ ododó, a si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a si ṣe ikede niwaju rẹ̀ pe, ki a fi i ṣe olori ẹkẹta ni ijọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Beliṣáṣárì pàṣẹ pé kí a wọ Dáníẹ́lì ní aṣọ eléṣèé àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀.