Daniel 6:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn dahùn nwọn si wi niwaju ọba pe, Danieli ọkan ninu awọn ọmọ igbekun Juda kò kà ọ si, ọba, ati aṣẹ, nitori eyi ti iwọ fi ọwọ rẹ sinu iwe, ṣugbọn o ngbadura rẹ̀ nigba mẹta lõjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni wọ́n sọ fún ọba pé, “Dáníẹ́lì, ọ̀kan lára ìgbékùn Júdà, kò ka ìwọ ọba sí, tàbí àṣẹ ẹ̀ rẹ tí o fi ọwọ́ sí. Òun sì tún ń gba àdúrà ní ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́.”