Daniel 6:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bá lọ sí ààfin rẹ̀, ó fi gbogbo òru náà gbààwẹ̀. Kò jẹ́ kí àwọn eléré ṣe eré níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì lè sùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ọba padà sí ààfin rẹ̀, ó sì lo gbogbo òru náà láì jẹun, kò sì gbọ orin kankan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le è ṣùn ní òru ọjọ́ náà.