Daniel 6:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó dé ẹ̀bá ibẹ̀, ó kígbe pẹlu ohùn arò, ó ní, “Daniẹli, iranṣẹ Ọlọrun Alààyè, ǹjẹ́ Ọlọrun tí ò ń sìn láìsinmi gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn kinniun?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si sunmọ iho na o fi ohùnrére ẹkun kigbe si Danieli: ọba dahùn o si wi fun Danieli pe, Danieli! iranṣẹ Ọlọrun alãye! Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, ha le gbà ọ lọwọ awọn kiniun bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sún mọ́ ibi ihò náà ní ibi tí Dáníẹ́lì wà, ó pe Dáníẹ́lì pẹ̀lú ìtara pé, “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn tọ̀sán tòru, lè gbà ọ́ lọ́wọ́ ọ kìnnìún bí?”