Daniel 6:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun mi ti ran angeli rẹ̀, o si dì awọn kiniun na lẹnu, ti nwọn kò fi le pa mi lara: gẹgẹ bi a ti ri mi lailẹṣẹ niwaju rẹ̀; ati niwaju rẹ pẹlu, ọba, emi kò si ṣe ohun buburu kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run mi rán ańgẹ́lì i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pamí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.”