Daniel 6:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú ọba dùn pupọ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Daniẹli jáde. Wọ́n bá yọ Daniẹli jáde kúrò ninu ihò kinniun, àwọn kinniun kò sì pa á lára rárá, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ọba yọ̀ gidigidi, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o fà Danieli jade kuro ninu iho. Bẹ̃li a si fa Danieli jade kuro ninu iho, a kò si ri ipalara lara rẹ̀, nitoriti o gbà Ọlọrun rẹ̀ gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Inú ọba dùn gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a mú Dáníẹ́lì jáde wá láti inú ihò. Nígbà tí a mú Dáníẹ́lì jáde nínú ihò, kò sí ojú ọgbẹ́ kan ní ara rẹ̀, nítorí tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.