Daniel 6:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
mo pàṣẹ pé ní gbogbo ìjọba mi, kí gbogbo eniyan máa wárìrì níwájú Ọlọrun Daniẹli, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀. “Nítorí òun ni Ọlọrun Alààyè tí ó wà títí ayérayé. Ìjọba rẹ̀ kò lè parun lae, àṣẹ rẹ̀ yóo sì máa wà títí dé òpin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo paṣẹ pe, Ni gbogbo igberiko ijọba mi, ki awọn enia ki o ma warìri, ki nwọn si ma bẹ̀ru niwaju Ọlọrun Danieli, nitoripe on li Ọlọrun alãye, on si duro lailai, ati ijọba rẹ̀, eyi ti a kì yio le parun ni, ati agbara ijọba rẹ̀ yio si wà titi de opin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mo gbé àsẹ kan jáde wí pé: ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì. “Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè Ó sì wà títí ayé; Ìjọba rẹ̀ kò le è parun ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun