Daniel 6:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi wipe, Awa kì yio le ri ẹ̀sùn kan si Danieli bikoṣepe a ba ri i si i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, “Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀.”