Daniel 7:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si fi agbara ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sìn i; agbara ijọba rẹ̀ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a kì yio rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyiti a kì yio le parun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.