Daniel 7:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Mo tún fẹ́ mọ̀ nípa ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù, tí ó bani lẹ́rù lọpọlọpọ, tí èékánná rẹ̀ jẹ́ idẹ, tí eyín rẹ̀ sì jẹ́ irin; tí ń jẹ àjẹrun, tí ó ń fọ́ nǹkan túútúú, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni mo si nfẹ imọ̀ otitọ ti ẹranko kẹrin, eyiti o yatọ si gbogbo awọn iyokù, ti o lẹrù gidigidi, eyi ti ehin rẹ̀ jẹ irin, ti ẽkanna rẹ̀ jẹ idẹ, ti njẹ, ti nfọ tũtu, ti o si nfi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtúmọ̀ òtítọ̀ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yóòkù, èyí tí ó dẹ́rù ba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀.