Daniel 7:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A óo fi ìjọba ati àṣẹ, ati títóbi àwọn ìjọba tí ó wà láyé fún àwọn eniyan mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ, ìjọba ayérayé ni ìjọba wọn yóo jẹ́, gbogbo àwọn aláṣẹ yóo máa sìn ín, wọn yóo sì máa gbọ́ tirẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ijọba, ati agbara ijọba ati ipa gbogbo ijọba ni gbogbo abẹ-ọrun, li a o si fi fun enia awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo, ijọba ẹniti iṣe ijọba ainipẹkun, ati gbogbo awọn alakoso ni yio ma sìn, ti nwọn o si ma tẹriba fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn ọ̀gá ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’