Daniel 7:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí mo ti ń ronú nípa àwọn ìwo rẹ̀, ni mo rí i tí ìwo kékeré kan tún hù láàrin wọn, ìwo mẹta fà tu níwájú rẹ̀ ninu àwọn ìwo ti àkọ́kọ́. Ìwo kékeré yìí ní ojú bí eniyan, ó sì ní ẹnu tí ó fi ń sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárin wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fà tu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.