Daniel 8:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni mímọ́ kan sọ̀rọ̀; mo tún gbọ́ tí ẹni mímọ́ mìíràn dá ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ lóhùn pé, “Ìran nípa ẹbọ sísun ojoojumọ yóo ti pẹ́ tó; ati ti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń sọ nǹkan di ahoro; ati ìran nípa pípa ibi mímọ́ tì, ati ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún-un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúsẹ-ìran nípa ẹbọ ojojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó ń sọ dahoro, àti mímú kí ibi mímọ́ àti ẹgbẹ́ ogun ọ̀run di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”