Daniel 8:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó wá sí ẹ̀bá ibi tí mo dúró sí. Bí mo ti rí i, ẹ̀rù bà mí, mo dojúbolẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la ni ohun tí o rí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bàmí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”