Daniel 8:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìtumọ̀ ìwo tí ó ṣẹ́, tí mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀, ni pé lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni ìjọba rẹ̀ yóo pín sí mẹrin, ṣugbọn kò ní jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwo mẹ́rin ti ó dípo ọ̀kan tí ó kán dúró, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí ó dìde láti orílẹ̀ èdè e rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò ní ní irú agbára kan náà.