Daniel 8:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Agbára rẹ̀ yóo pọ̀, ṣugbọn kò ní jẹ́ nípa ipá rẹ̀, yóo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó bá ń ṣe, yóo sì mú kí á run àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn alágbára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Agbara rẹ̀ yio si le gidigidi, ṣugbọn kì iṣe agbara ti on tikararẹ̀: on o si ma ṣe iparun ti o yani lẹnu, yio si ma ri rere ninu iṣẹ, yio si pa awọn alagbara ati awọn enia ẹni-mimọ́ run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò di alágbára, ṣùgbọn tí kì í ṣe nípa agbára rẹ̀. Yóò sì máa ṣe ìparun tí yóò ya ni lẹ́nu, yóò sì máa ṣe àṣeyọri nínú ohun gbogbo tó ń ṣe. Yóò sì run àwọn alágbára àti àwọn ènìyàn mímọ́.