Daniel 8:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nípa ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, yóo máa tan àwọn eniyan jẹ, ìgbéraga yóo kún ọkàn rẹ̀, yóo máa pa ọpọlọpọ eniyan lójijì, yóo sì lòdì sí ọba tí ó ju gbogbo àwọn ọba lọ. Ṣugbọn yóo parun láìní ọwọ́ ẹnikẹ́ni ninu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nipa arekereke rẹ̀ yio si mu ki iṣẹ ẹ̀tan ṣe dẽde lọwọ rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga li ọkàn rẹ̀, lojiji ni yio si pa ọ̀pọlọpọ run, yio dide si olori awọn ọmọ-alade nì; ṣugbọn on o ṣẹ́ laisi ọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa àrékérekè rẹ̀, yóò mú kí ẹ̀tàn gbèrú, yóò gbé ara rẹ̀ ga nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n rò wí pé àlàáfíà dé, yóò sì pa àwọn ènìyàn run, nígbà tí wọn kò rò tẹ́lẹ̀, yóò sì lòdì sí olórí àwọn ọmọ aládé, ṣíbẹ̀, a ó paárun ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa agbára ènìyàn.