Daniel 8:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àárẹ̀ mú èmi Daniẹli, mo sì ṣàìsàn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Nígbà tó yá, mo bá tún dìde, mò ń bá iṣẹ́ tí ọba yàn mí sí lọ, ṣugbọn ìran náà dẹ́rù bà mí, kò sì yé mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Arẹ̀ si mu emi Danieli, ara mi si ṣe alaida niwọn ọjọ melokan; lẹhin na, mo dide, mo si nṣe iṣẹ ọba; ẹ̀ru si bà mi, nitori iran na, ṣugbọn kò si ẹni ti o fi ye mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi Dáníẹ́lì sì ṣe àárẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Nígbà náà, mo dìde, mo sì ń bá isẹ́ ọba lọ. Ìran náà sì bàmí lẹ́rù, kò sì yé mi.