Daniel 8:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo rí i tí àgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, kò sí ẹranko tí ó lè dúró níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti wù ú, ó sì ń gbéraga.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, sí àríwá, àti sí gúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó leè dojú kọọ́, kò sí ẹnìkan tí ó leè yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.