Daniel 9:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, ìwọ tí o kó àwọn eniyan rẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu agbára ńlá, nítorí orúkọ rẹ tí à ń ranti títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe nǹkan burúkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, iwọ ti o ti fi ọwọ agbara mu awọn enia rẹ jade lati Egipti wá, ti iwọ si ti gba orukọ fun ara rẹ gẹgẹ bi o ti wà loni: awa ti ṣẹ̀, awa si ti ṣe buburu gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ìsinsin yìí, OLÚWA Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búrurú.