Daniel 9:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, ṣí ojurere wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, gbọ́ adura ọmọ-ọdọ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, ki o si mu ki oju rẹ ki o mọlẹ si ibi-mimọ́ rẹ ti o dahoro, nitori ti Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nísinsinyìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ OLÚWA, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro.