Daniel 9:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin ọ̀sẹ mejilelọgọta na li a o ke Ẹni-ororo na kuro, kì yio si si ẹnikan fun u, ati awọn enia ọmọ-alade kan ti yio wá ni yio pa ilu na ati ibi-mimọ́ run; opin ẹniti mbọ yio dabi ikún omi, ati ogun titi de opin, eyi ni ipari idahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ̀yìn ọ̀ṣẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn alákòóso tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi: ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro.