Daniel 9:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ OLUWA Ọlọrun tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ mò ń gbadura tọkàntọkàn pẹlu ààwẹ̀; mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo sì jókòó sinu eérú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si kọju mi si Oluwa Ọlọrun, lati ma ṣafẹri nipa adura ati ẹ̀bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ẽru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ni mo yípadà sí OLÚWA Ọlọ́run, mo bẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ààwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.