Deuteronomy 1:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Mo pàṣẹ fún àwọn adájọ́ yín nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ àwọn arakunrin yín, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo láàrin eniyan ati arakunrin rẹ̀, tabi àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si fi aṣẹ lelẹ fun awọn onidajọ nyin nigbana pe, Ẹ ma gbọ́ ẹjọ́ lãrin awọn arakunrin nyin, ki ẹ si ma ṣe idajọ ododo lãrin olukuluku ati arakunrin rẹ̀, ati alejò ti mbẹ lọdọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé: Ẹ gbọ́ èdè àìyedè tí ó wà láàrin àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin Ísírẹ́lì sí Ísírẹ́lì ni tàbí láàrin Ísírẹ́lì kan sí àlejò.