Deuteronomy 1:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju ni idajọ; ẹ gbọ́ ti ewe gẹgẹ bi ti àgba; ẹ kò gbọdọ bẹ̀ru oju enia; nitoripe ti Ọlọrun ni idajọ: ọ̀ran ti o ba si ṣoro fun nyin, ẹ mú u tọ̀ mi wá, emi o si gbọ́ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má sì se ojúṣàájú ní ìdájọ́: Ẹ ṣe ìdájọ́ ẹni ńlá àti kékeré bákan náà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹnikẹ́ni torí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́. Ẹjọ́ tí ó bá le jù fún un yín ni kí ẹ mú wá fún mi. Èmi yóò sì gbọ́ ọ.