Deuteronomy 1:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awa si kuro ni Horebu, awa rìn gbogbo aginjù nla nì ti o ni ẹ̀ru já, ti ẹnyin ri li ọ̀na òke awọn ọmọ Amori, bi OLUWA Ọlọrun wa ti fun wa li aṣẹ; awa si wá si Kadeṣi-barnea.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ní a gbé ra láti Horebu, bí OLÚWA Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wá, a sì la àwọn ilẹ̀ lókè Ámórì kọjá lọ dé gbogbo aṣálẹ̀ ńlá tí ó ba ni lẹ́rù nì tí ẹ̀yin ti rí, bẹ́ẹ̀ ni a sì dé Kádésì Báníyà.