Deuteronomy 1:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ilẹ̀ náà ni OLUWA Ọlọrun yín tẹ́ kalẹ̀ níwájú yín yìí, mo ní kí ẹ gbéra, kí ẹ lọ gbà á, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín ti sọ fun yín. Mo ní kí ẹ má bẹ̀rù rárá, kí ẹ má sì fòyà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kíyèsìí, OLÚWA Ọlọ́run yín ló ní ilẹ̀ náà. Ẹ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà bí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín tí sọ fún un yín. Ẹ má bẹ̀rù, Ẹ má sì ṣe fòyà.”