Deuteronomy 1:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ká ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀, wọ́n sì jábọ̀ fún wa pé ilẹ̀ dáradára ni OLUWA Ọlọrun wa fi fún wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mú ninu eso ilẹ na li ọwọ́ wọn, nwọn si mú u sọkalẹ wá fun wa, nwọn si mú ìhin pada wá fun wa, nwọn si wipe, Ilẹ ti OLUWA wa fi fun wa, ilẹ rere ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni OLÚWA Ọlọ́run wa fún wa.”