Deuteronomy 1:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kùn ninu àgọ́ yín, ẹ ní, ‘Ọlọrun kò fẹ́ràn wa, ni ó ṣe kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, kí ó lè kó wa lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin si kùn ninu agọ́ nyin, wipe, Nitoriti OLUWA korira wa, li o ṣe mú wa lati Egipti jade wá, lati fi wa lé ọwọ́ awọn ọmọ Amori, lati run wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “OLÚWA kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Éjíbítì láti fi wá lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́ láti pa wá run.