Deuteronomy 1:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà náà, ẹ dá mi lóhùn, ẹ ní, ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA, nítorí náà, ẹ óo dìde, ẹ óo sì lọ jagun, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fun yín. Olukuluku yín bá múra láti jagun, gbogbo èrò yín nígbà náà ni pé kò ní ṣòro rárá láti ṣẹgun àwọn tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li ẹ dahùn, ẹ si wi fun mi pe, Awa ti ṣẹ̀ si OLUWA, awa o gòke lọ, a o si jà, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa palaṣẹ fun wa. Ati olukuluku nyin dì ihamọra ogun rẹ̀, ẹnyin mura lati gùn ori òke na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ẹ fèsì wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí OLÚWA. A ó sì gòkè lọ láti jà, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún wa.” Torí náà gbogbo yín ẹ mú ohun ìjà a yín, ẹ rò pé ó rọrùn láti gòkè lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè olókè náà.