Deuteronomy 1:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Amori tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà bá jáde sí yín, wọ́n le yín bí oyin tíí lé ni, wọ́n sì pa yín ní ìpakúpa láti Seiri títí dé Horima.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Amori, ti ngbé ori òke na, si jade tọ̀ nyin wá, nwọn si lepa nyin, bi oyin ti iṣe, nwọn si run nyin ni Seiri, titi dé Horma.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Ámórì tí ń gbé ní àwọn òkè náà, dojú kọ yín bí àgbájọpọ̀ oyin. Wọ́n sì lù yín bolẹ̀ látí Séírì títí dé Hómà.