Deuteronomy 1:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ yípadà kí ẹ sì tẹ̀ṣíwájú ní ìrìnàjò yín lọ sí ilẹ̀ òkè àwọn ará Ámórì: Ẹ tọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń gbé agbégbé lọ ní aginjù, ní àwọn orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní Nágéfì àti ní etí òkun, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kénánì àti lọ sí Lẹ́bánónì, títí fi dé odò ńlá Éfúrétì.