Deuteronomy 1:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, mo ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọ̀ ọ lọ ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn lẹhin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó, èmi tí fi ilẹ̀ yí fún un yín: Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí OLÚWA ti wí pé òun yóò fún àwọn baba yín: fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti fún àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn.”