Deuteronomy 10:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, kò sí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fẹ́ kí ẹ ṣe, àfi pé kí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkàn yín ati ẹ̀mí yín,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, Israeli, kini OLUWA Ọlọrun rẹ mbère lọdọ rẹ, bikoṣe lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, lati ma fẹ́ ẹ, ati lati ma sìn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsin yìí ìwọ Ísírẹ́lì, kín ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin OLÚWA Ọlọ́run rẹ ọkan àti àyà rẹ,