Deuteronomy 10:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá kọ àwọn òfin mẹ́wàá tí ó kọ sí ara àwọn tabili àkọ́kọ́ sára àwọn tabili náà, ó sì kó wọn fún mi. Àwọn òfin mẹ́wàá yìí ni OLUWA sọ fun yín lórí òkè láti ààrin iná ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si kọ ofin mẹwẹwa sara walã wọnni, gẹgẹ bi o ti kọ ti iṣaju, ti OLUWA sọ fun nyin lori òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì; OLUWA si fi wọn fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí síléétì wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. OLÚWA sì fi wọ́n fún mi.