Deuteronomy 10:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, mo sì kó àwọn tabili náà sinu àpótí tí mo kàn, wọ́n sì wà níbẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke na wá, mo si fi walã wọnni sinu apoti ti mo ti ṣe; nwọn si wà nibẹ̀, bi OLUWA ti paṣẹ fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn síléètì òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí OLÚWA ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.