Deuteronomy 10:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
(Àwọn eniyan Israẹli rìn láti Beeroti Benejaakani lọ sí Mosera, ibẹ̀ ni Aaroni kú sí, tí wọ́n sì sin ín sí. Eleasari ọmọ rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alufaa dípò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
(Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati Beerotu ti iṣe ti awọn ọmọ Jaakani lọ si Mosera: nibẹ̀ li Aaroni gbé kú, nibẹ̀ li a si sin i; Eleasari ọmọ rẹ̀ si nṣe iṣẹ alufa ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Àwọn ará Ísírẹ́lì sì gbéra láti kàǹga àwọn ará a Jákánì dé Mósérà. Níbí ni Árónì kú sí, tí a sì sin ín, Élíásárì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà.