Deuteronomy 10:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò yìí, OLUWA ya àwọn ẹ̀yà Lefi sọ́tọ̀ láti máa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA, ati láti máa dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, ati láti máa yin orúkọ rẹ̀, títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà yí ni OLÚWA yan àwọn ọmọ Léfì láti máa ru àpótí májẹ̀mú OLÚWA, láti máa dúró níwájú OLÚWA láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ OLÚWA súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí.