Deuteronomy 11:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà yìí, kò rí bí ilẹ̀ Ijipti níbi tí ẹ ti jáde wá; níbi tí ó jẹ́ pé nígbà tí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn yín tán, ẹ óo ṣe wahala láti bu omi rin ín, bí ìgbà tí à ń bu omi sí ọgbà ẹ̀fọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, kò dabi ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin ti jade wá, nibiti iwọ gbìn irugbìn rẹ, ti iwọ si nfi ẹsẹ̀ rẹ bomirin i, bi ọgbà ewebẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Éjíbítì, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹṣẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bominrin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́.