Deuteronomy 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun búra fún àwọn baba yín, pé òun yóo fún wọn títí lae, níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá wà lókè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ọjọ́ nyin ki o le ma pọ̀si i, ati ọjọ́ awọn ọmọ nyin, ni ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin lati fi fun wọn, bi ọjọ́ ọrun lori ilẹ aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí OLÚWA ti búra láti fifún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìṣàlẹ̀.