Deuteronomy 11:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju nyin: OLUWA Ọlọrun nyin, yio fi ìbẹru nyin ati ìfoiya nyin sara gbogbo ilẹ ti ẹnyin o tẹ̀, bi on ti wi fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.