Deuteronomy 11:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ègún ni fun yín bí ẹ kò bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ bá yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fun yín lónìí, tí ẹ bá ń sin àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati egún, bi ẹnyin kò ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́ ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tíì mọ̀.