Deuteronomy 11:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ẹ óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fi fun yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á tán, tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ẹnyin o gòke Jordani lati wọle ati lati gbà ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin, ẹnyin o si gbà a, ẹnyin o si ma gbé inu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ ti ṣetan láti la Jọ́dánì kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run yín ń fún un yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀,