Deuteronomy 11:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ohun tí ó ṣe sí Dátanì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù, ẹ̀yà Rúbẹ́nì, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Ísírẹ́lì tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn.