Deuteronomy 12:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Àwọn ìlànà ati òfin, tí ẹ óo máa tẹ̀lé lẹ́sẹẹsẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fi fun yín láti gbà, nìyí:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
WỌNYI ni ìlana ati idajọ, ti ẹnyin o ma kiyesi lati ma ṣe ni ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ fi fun ọ lati ní, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà lori ilẹ-aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà àti òfin tí ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra láti máa tẹ̀lé, ní ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín, fi fún un yín láti gbà: ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ náà.