Deuteronomy 12:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn láti fi ibùgbé rẹ̀ sí nígbà náà, ni kí ẹ kó gbogbo àwọn nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín wa, ẹbọ sísun yín ati àwọn ẹbọ mìíràn, ìdámẹ́wàá yín, ati ọrẹ, ati gbogbo ẹ̀jẹ́ yín tí ẹ bá jẹ́ fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbi tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ síṣún, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLÚWA.