Deuteronomy 12:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bikoṣe ki iwọ ki o jẹ wọn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ: ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ninu ohun gbogbo ti iwọ fi ọwọ́ rẹ le.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín, níbi tí OLÚWA Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́-kùnrin àti ìránṣẹ́-bìnrin rẹ àti àwọn Léfì láti ìlú u yín: kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín.