Deuteronomy 12:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo lé kúrò ti ń sin oriṣa wọn ni kí ẹ wó lulẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà lórí òkè ńlá, ati àwọn tí wọ̀n wà lórí àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ igi tútù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o run ibi gbogbo wọnni patapata, nibiti awọn orilẹ-ède nì, ti ẹnyin o gbà, nsìn oriṣa wọn, lori òke giga, ati lori òke kekeké, ati labẹ igi tutù gbogbo:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ibi gíga àwọn òkè ńlá, àti òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹ ó lé jáde, tí ń sin òrìṣà wọn ní kí ẹ mú kúrò pátapáta.