Deuteronomy 12:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ti iwọ ba si wipe, Emi o jẹ ẹran, nitoriti ọkàn rẹ nfẹ́ ẹran ijẹ; ki iwọ ki o ma jẹ ẹran, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí OLÚWA Ọlọ́run yín bá ti fẹ́ agbègbè e yín bí ó ti ṣe ìlérí, fún un yín, tí ẹ sì wí pé, àwa yóò jẹ ẹran, nítorí tí ọkàn wa fẹ́ jẹran. Ẹ jẹ ẹran náà bí ẹ tí fẹ́.